Hosea 6

Àìronúpìwàdà Israẹli

1“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa
ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá
Ó ti pa wá lára
ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.
2Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí
ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò
kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀
3Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa
Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,
Yóò jáde;
Yóò tọ̀ wá wá bí òjò
bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

4“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?
Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?
Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀
bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
5Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.
Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi
Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín
6 aNítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;
àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.
7Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú
wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.
8Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú
tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.
9Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀;
tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu,
tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.
10Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù
ní ilé Israẹli.
Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè
Israẹli sì di aláìmọ́.

11“Àti fún ìwọ, Juda
A ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ.

“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,
Copyright information for YorBMYO